Ìtàn mánigbàgbé: sango gbèrò ibi fún gbonka àti timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ - bbc news yorùbá

Bbc

Ìtàn mánigbàgbé: sango gbèrò ibi fún gbonka àti timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ - bbc news yorùbá"

Play all audios:

Loading...

ÌTÀN MÁNIGBÀGBÉ: SANGO GBÈRÒ IBI FÚN GBONKA ÀTI TIMI, ÀMỌ́ ÒUN GAN BÁ Ọ̀TẸ̀ NÁÀ LỌ 8 Bélú 2019 Ìgbà tí a ṣe àfíkun gbẹ̀yìn 9 Bélú 2019 ẸLẸDAA FI ỌPỌ AWỌN AKỌNI NLA JINKI ILẸ YORUBA LAYE


ATIJỌ. Awọn naa ni arogun matidi, abawọnja ma se ojo, awọn ti ilu ṣee gbọkanle, iru wọn si ni Timi Agbale Ọlafa ina ati Gbọnka Ebiri. Timi Agbale ati Gbọnka Ebiri jẹ akọni ọdẹ aperin ati


jagunjagun ni Ọyọ atijọ, ti wọn ko si lee kọ iyan wọn, ki wọn ma fi ewe boo, ti itan si sọ fun wa pe Timi lo da ilu Ẹdẹ, to wa nipinlẹ Ọṣun silẹ. ÀWỌN IRÒYIN TÌ Ẹ LEÈ NÍ ÌFẸ̀ SÍÍ: * Ìlàná


ìṣúná tí yóò mú aráàlú kúrò nínú àìní bọ́ sí ọ̀pọ̀ là fẹ́ gbékalẹ̀ - Seyi Makinde * Ọmọ ogun Nàìjíríà mẹ́wàá dèrò ọ̀run lẹ́yìn ìkọlù ẹgbẹ́ Boko Haram * A ó pe àjọ DSS lẹjọ́ tí wọ́n bá kọ̀


láti tú Sowore sílẹ̀ - Falana * Ìyàwó mi kórira kí Odunlade Adekola máa bú mi nínú eré tíátà - Ijebu * Àlàáfíà padà sí Ile Ife lẹ́yìn ikú awakùṣà méjì tó fa rògbòdìyàn Gẹgẹ baa se kaa loju


opo itakun agbaye, taa si rii gbọ ninu itan atẹnudẹnu, a lee tọpasẹ itan Gbọnka ati Timi Agbale si ọdun 1500. Eyi jẹ lasiko to n lo ọfa to maa n yọ ina lati fi ja ogun, idi si niyi ti wọn ṣe


n pe e ni Timi Agbale Ọlọfa ina. Skip Èyítí A Ń Kà Jùlọ and continue reading ÈYÍTÍ A Ń KÀ JÙLỌ * Ká ní mo mọ̀ pé ọkọ mi yóò lọ kò ní dé padà, mi ò bá májẹ kó jáde - aya Abdulfatai tí ògiri


wò pa ni Kwara * Àgbàrá òjò gbé èèyàn mọ́kànlá lọ l'Ámérika, ọ̀pọ̀ di àwátì * Fifa Club World Cup: Báyìí ni ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù káàkiri àgbáyé yóò ṣe lọ * Wo bí fóònù


ṣe ń ṣokùnfà ikú àwọn obìnrin tó wà nílé ọkọ ní Niger End of Èyítí A Ń Kà Jùlọ Gbọnka Ebiri ni tiẹ kii lo ọfa lati jagun amọ o ni oogun ju Arọni lọ, eyi to maa n lo lati fi sẹgun ọta. Itan


naa sọ fun wa pe, Timi Agbale jẹ ọrẹ timọ-timọ fun Gbọnka Ebiri, ti awọn mejeeji si jẹ jagunjagun laye igba ti Alaafin Sango n jọba. BI ITAN IGBE AYE TIMI AGBALE ỌLỌFA INA ATI GBỌNKA EBIRI


SE LỌ REE: * Apetan orukọ Timi Agbale ni Timi Kubọlajẹ Agbọnran, ti orukọ baba rẹ si n jẹ Lalẹmọ. Awọn ọmọ baba rẹ ni Oyefi, Ajẹnju, Arohanran ati Oduniyi * Timi Agbale bi ọmọkunrin meji amọ


ti itan ko sọ ohunkohun fun wa nipa Gbọnka Ebiri. * Timi Agbale ati ọrẹ rẹ, Gbọnka Ebiri jẹ alagbara nla ni Ọyọ ile, to si de akoko kan ti agbara Alaafin Sango ko fẹ ka wọn mọ, ti ẹru si n


ba a pe awọn mejeeji le pa oun tabi le oun kuro lori itẹ. * Idi ree ti Alaafin Sango fi n wa ọna lati ya ọrẹ korikosun mejeeji naa, to si ni ki wọn ran Timi Agbale to buru julọ laarin awọn


mejeeji nisẹ iku ti ko ni lee pada de mọ. * Eyi lo mu ki Alaafin Sango ran Timi Agbale lati lọ dena de awọn agbesunmọmi to wa lati ilẹ Ijẹsa laarin ilu Arà ati Awó, pẹlu igbagbọ pe wọn yoo


pa a nibẹ. * Timi Agbale ko fura pe isẹ iku ni Ọba ran oun, to si lọ lai se awawi kankan pẹlu awọn ọmọ ogun rẹ, to si lọ tẹdo si abẹ igi kan ti wọn n pe ni Ẹdẹ, eyi to wa laarin ilu Arà ati


Awó. Ilu naa si la n pe ni ilu Ẹdẹ, eyi to wa titi di oni oloni * Asiko ti Timi Agbale wa nibudo yii ni alaafia jọba lagbegbe naa, ti awọn agbesunmọmi ko si wa da agbegbe naa laamu mọ, eyi


to mu ko ransẹ si Alaafin Sango pe se oun lee maa pada bọ wale * Alaafin Sango ni ki Timi Agbale duro si agbegbe naa, to si tun fọwọsi i pe ko maa gba owo ẹyọ marun un bii owo ibode lawọn


agbegbe yii, ko si maa mu isakọlẹ wa fun oun. * Timi Agbale n fi isakọlẹ ransẹ si Alaafin Sango fun igba diẹ, nigba to ya, lo ba faake kọri pe oun ko ni fi isakọlẹ kankan ransẹ mọ si


Alaafin. * Eyi to mu ki Ọba gbe onisẹ kan dide, Tọbalagbọ, lati lọ wadii ohun to mu ki Timi dawọ sisan isakọlẹ duro. * Timi sọ fun onisẹ Alaafin pe oun ti faake kọri lati san isakọlẹ fun


Alaafin, to si ran wọn pada silu Ọyọ lọwọ ofo, ti isẹlẹ naa si bọ si apo ibinu Ọba * Alaafin Sango wa ran ikọ ọmọogun kekere kan lọ kọlu Timi ni Ede, ko lee mọ pe Ọba ba lori ohun gbogbo amọ


ajẹkun iya ni awọn onisẹ Alaafin jẹ, ti Timi si lu wọn bi ẹni lu bara. * Ojuti nla ni eyi jẹ fun ori ade naa, to si ro pe o seese ki Timi, ti wọn n pe ni Ẹlẹdẹ nigba naa wa doju ijọba oun


bolẹ laipẹ. * Idi ni yii to fi ronu pe ẹnikansoso to lee ge iyẹ apa Timi ni ọrẹ minu rẹ, Gbọnka Ebiri nitori ole nii mọ ẹsẹ ole tọ lori apata. * Alaafin Sango sọ iwa orikunkun ti Timi Agbale


hu si i fun Gbọnka, to si ni ko lọ mu u wa silu Ọyọ; amọ se ni Ọba pe awọn ọmọogun to n tẹle Gbọnka lọ si Ẹdẹ sẹyin, to si pasẹ pé wọn gbọdọ ri i daju pe wọn pa a eyi ti ko han si Gbọnka


funra rẹ. * Awọn ọmọ ogun ọrẹ korikosun wọya ija, ti apa Timi si n lewaju, eyi to mu ki awọn ọmọ ogun Gbọnka sa sẹyin fun igba meji, lẹyin o rẹyin, wọn pinnu pe awọn olori ogun mejeeji ni ki


wọn koju ija sira wọn, kawọn lee mọ ẹni ti yoo sẹgun * Gbọnka, gẹgẹ bii jagunjagun to ni oogun, pasẹ pe ki Timi sun lọ fọnfọn lasiko ija naa, to si di i tọwọ tẹsẹ lọ silu Ọyọ. Alaafin Sango


ki i ku ogun ajaye amọ isẹlẹ naa ko dun mọ ọ ninu rara, to si pe awọn Ọyọmesi rẹ lati fun un ni imọran lori ohun to yẹ ko se lati rẹyin awọn jagunjagun alagbara mejeeji. * Awọn Ọyọmesi gba


Alaafin Sango nimọran pe ko tako ija ti awọn ọrẹ meji naa ja ni Ẹdẹ, ko si pasẹ pe ki wọn tun ija naa ja nilu Ọyọ niwaju Ọba ati awọn Ọyọmesi * Ọjọ Akẹsan ni wọn tun ti fija pẹẹta, Timi ta


ọfa rẹ, to si tase Gbọnka, ti onitọun naa si lo oogun lati fi mu ki Timi sunlọ fọnfọn, to si bẹ ori rẹ. Ẹ̀ wo bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú etí òkun ṣe ń ṣiṣẹ́ l'Eko World water day: Ẹrin Ijesa,


Ọ̀ṣun Oṣogbo, àwọn ibùdó ìgbafẹ́ omi tí ó yẹ kí o mọ̀ Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa D.O Fágúnwà? Afárá odo ọya keji :Ta ni yóò parí rẹ? * Bi Timi Agbale Ọlọfa Ina se jade laye ree, ti inu ọrẹ rẹ ko si


dun si isẹlẹ naa rara, eyi to mu ko ransẹ si Alaafin Sango pe ko fi ori apere silẹ tabi ko ṣí igba wo, eyi to tumọ si pe ko ku nitori iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni. * Gbọnka


sọ fun Alaafin pe ko si agbara kankan to le le oun kuro nilu Ọyọ, ti Ọba ba si fẹ mọ bi irọ ni ọrọ naa abi tootọ, ko da ina nla kan silẹ, ko si pasẹ pe ki wọn gbe oun sinu rẹ * Inu Ọba dun


si imọran naa, to si ṣe bẹẹ gẹẹ. * Bi wọn se ju Gbọnka sinu ina lo jona di eeru patapata, ti Alaafin si n fo fayọ pe oun ri ẹyin ọta oun mejeeji, amọ oju ẹsẹ ni Gbọnka jade pe oun ko ku, to


si pasẹ pe Alaafin Sango pe ko se bi ọkunrin. * Ọba wa ri pe ko si abuja miran lẹyin ọpẹ mọ, idi ree to fi wọlẹ lọ, ti wọn si n bọ Alaafin Sango ni ọrọọrun, taa mọ si ọjọ marun marun, ta mọ


si ọjọ Jakuta. * Lẹyin o rẹyin, ko sẹni to mọ ohun to sẹlẹ si Gbọnka mọ, ti oun naa si pada di ara ilẹ. ÀWỌN IRÒYIN TÌ Ẹ LEÈ NÍ ÌFẸ̀ SÍÍ: * Omi ìṣẹ̀ńbáyé tó ń dà ní Ówù rèé, èyí tó ga jùlọ


ní Afirika * 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò' * Mo ti sọ ìran nípa ọkọ aképo tó gbiná ní Onitsha kó tó ṣẹlẹ̀ - Primate Ayodele * Àlá àwọn òjíṣẹ́


Olúwa tó fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà leè má ṣẹ lógún ọdún - Abiara * Ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá, omi máa ń bọ́ lójú mi tí mo bá rántí àkókò náà - Small Doctor


Trending News

Ìjọba katsina yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé - bbc news yorùbá

ÌJỌBA KATSINA YÓÒ BẸ̀RẸ̀ SÍ Ń FI AJÁ ṢỌ́ ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ LÁTI KOJÚ ÀWỌN AJÍNIGBÉ 20 Ìgbé 2021 IJỌBA IPINLẸ KATSINA TI S...

Erosion in ilorin: kòtò tó wà níbí jìn ju ilé ìgbẹ́ lọ́! Ẹ̀mí wa ò tiẹ̀ balẹ̀ mọ́ - bbc news yorùbá

EROSION IN ILORIN: KÒTÒ TÓ WÀ NÍBÍ JÌN JU ILÉ ÌGBẸ́ LỌ́! Ẹ̀MÍ WA Ò TIẸ̀ BALẸ̀ MỌ́ 7 Ìgbé 2021 AWỌN ARA ILU N KEW GBAJA...

Olamide ogunade charcoal artist: bí mo ṣe ń lo ẹrọ ayélujára fi ran títa àwòrán mi lọ́wọ́ - bbc news yorùbá

OLAMIDE OGUNADE CHARCOAL ARTIST: BÍ MO ṢE Ń LO ẸRỌ AYÉLUJÁRA FI RAN TÍTA ÀWÒRÁN MI LỌ́WỌ́ 24 Ẹrẹ̀nà 2021 OLAMIDE OGUNAD...

Ìtàn mánigbàgbé: sango gbèrò ibi fún gbonka àti timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ - bbc news yorùbá

ÌTÀN MÁNIGBÀGBÉ: SANGO GBÈRÒ IBI FÚN GBONKA ÀTI TIMI, ÀMỌ́ ÒUN GAN BÁ Ọ̀TẸ̀ NÁÀ LỌ 8 Bélú 2019 Ìgbà tí a ṣe àfíkun gbẹ...

Walpurgis

This after sunset summer light is the closest we can come to the strangeness of a white night its borrowed time in which...

Latests News

Erosion in ilorin: kòtò tó wà níbí jìn ju ilé ìgbẹ́ lọ́! Ẹ̀mí wa ò tiẹ̀ balẹ̀ mọ́ - bbc news yorùbá

EROSION IN ILORIN: KÒTÒ TÓ WÀ NÍBÍ JÌN JU ILÉ ÌGBẸ́ LỌ́! Ẹ̀MÍ WA Ò TIẸ̀ BALẸ̀ MỌ́ 7 Ìgbé 2021 AWỌN ARA ILU N KEW GBAJA...

Walpurgis

This after sunset summer light is the closest we can come to the strangeness of a white night its borrowed time in which...

Ìtàn mánigbàgbé: sango gbèrò ibi fún gbonka àti timi, àmọ́ òun gan bá ọ̀tẹ̀ náà lọ - bbc news yorùbá

ÌTÀN MÁNIGBÀGBÉ: SANGO GBÈRÒ IBI FÚN GBONKA ÀTI TIMI, ÀMỌ́ ÒUN GAN BÁ Ọ̀TẸ̀ NÁÀ LỌ 8 Bélú 2019 Ìgbà tí a ṣe àfíkun gbẹ...

Ìjọba katsina yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń fi ajá ṣọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti kojú àwọn ajínigbé - bbc news yorùbá

ÌJỌBA KATSINA YÓÒ BẸ̀RẸ̀ SÍ Ń FI AJÁ ṢỌ́ ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ LÁTI KOJÚ ÀWỌN AJÍNIGBÉ 20 Ìgbé 2021 IJỌBA IPINLẸ KATSINA TI S...

Olamide ogunade charcoal artist: bí mo ṣe ń lo ẹrọ ayélujára fi ran títa àwòrán mi lọ́wọ́ - bbc news yorùbá

OLAMIDE OGUNADE CHARCOAL ARTIST: BÍ MO ṢE Ń LO ẸRỌ AYÉLUJÁRA FI RAN TÍTA ÀWÒRÁN MI LỌ́WỌ́ 24 Ẹrẹ̀nà 2021 OLAMIDE OGUNAD...

Top